1- Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
1- Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
2- Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
3- Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.[998]
4- Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
5- Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
6- (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
7- A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
8- Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
9- (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
10- A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
11- Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
12- Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
13- Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
14- Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
15- Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
16- ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
17- Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
18- ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
19- Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
20- bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.