5- Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí. [4] Èyí ni àdéhùn ojoojúmọ́ tí à ń ṣe fún Allāhu, Ọlọ́hun tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún mùsùlùmí láti yapa àdéhùn náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa àdéhùn náà, ó ti di ẹlẹ́bọ pọ́nńbélé títí ó fi máa ronú pìwàdà.